1 Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun,fi ipá rẹ dá mi láre.
2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun;tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3 Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.
4 Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.