1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru.
2 Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?
5 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.