10 Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;
11 Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?
12 Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ.
13 Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrunninu ìmọ́lẹ̀ ìyè.