1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,nítorí ìwọ ni ààbò mi;abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá.
2 Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.
3 Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!
4 Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,ahọ́n wọn sì dàbí idà.