1 Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi;pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá;
2 dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú;kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà;
4 wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn,láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì.