15 N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ,èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run,n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ.
16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun,n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo ké pè é,mo sì kọrin yìn ín.
18 Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi,OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.
19 Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́;ó sì ti dáhùn adura mi.
20 Ìyìn ni fún Ọlọrun,nítorí pé kò kọ adura mi;kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.