9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.
10 Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ni Ọlọrun.
11 OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.
13 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.
14 Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò sì bìkítà fún ọ.
15 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.