1 Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà.
2 OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlúyòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu.
3 Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,ìwọ ìlú Ọlọrun.
4 Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni,Filistia ati Tire, ati Etiopia.Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”
5 A óo wí nípa Sioni pé,“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
6 OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọnnígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.”
7 Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”