3 Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.
4 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.
5 Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!
7 Nítorí òun ni Ọlọrun wa,àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,àwa ni agbo aguntan rẹ̀.Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,
8 ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀
9 nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ríohun tí mo ti ṣe rí.