10 Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”
11 Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.
12 Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin,
13 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.