2 Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.
3 OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.
4 Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.
5 N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,n ò kọ̀ kí ó nà mí;kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.
6 Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.
7 Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì.
8 Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.Ìwọ ni asà mi,má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò.