21 Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnìgbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù!
22 N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;kò sì ṣá wọn tì,bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.
25 Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.
26 Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!
27 Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.