26 Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!
27 Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.
28 Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
29 Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.
30 Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
31 Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,pé, “OLUWA ló ṣe é.”