2 Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?
3 Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”
4 Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́lọ sí ilé Ọlọrun;pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.
5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
6 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,nítorí náà mo ranti rẹláti òkè Herimoni,ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,
7 ìbànújẹ́ ń já lura wọn,ìdààmú sì ń dà gììrì,wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.
8 Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.