5 Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi,ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi.
6 O fẹ́ràn òtítọ́ inú;nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.
7 Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.
8 Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.
9 Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.
11 Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.