1 Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun.
2 Ò ń pète ìparun;ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè.
3 O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.
4 O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,Ìwọ ẹlẹ́tàn!
5 Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.
6 Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé,