5 Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.
6 Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé,
7 “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀,ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀,ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.”
8 Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútùtí ń dàgbà ninu ilé OLUWA,mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae.
9 N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae,nítorí ohun tí o ṣe,n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ,nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.