1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!
2 Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.
3 Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.
4 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.
5 Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.