1 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,tí kò rìn ní pa ìmọ̀ràn àwọn ènìyàn búburútàbí ti kò ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn pọ̀,tàbí ti kò si bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú Rẹ̀ wà nínú òfin Olúwaàti nínú òfin Rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí eti odò tí ń ṣàn,tí ń so èso Rẹ̀ jáde ní àkókò Rẹ̀tí ewé Rẹ̀ kì yóò Rẹ̀.Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé,ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkàtí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.