1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Síónì,tí a kò lè sí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
2 Bí òkè ńlá ti yí Jérúsálẹ́mù ká,bẹ́ẹ̀ ní Olúwa yí ènìyàn káláti ìsinsìnyí lọ àti títí láéláé.
3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburúkì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;kí àwọn olódodo kí o máa bafi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
4 Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Ísírẹ́lì.