1 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi olódì ẹ̀mí mi,ta ni ẹni tí èmi yóò bẹ̀rù?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí miláti jẹ ẹran ara mi,àní àwọn ọ̀ta mi àti àwọn abínúkú ù mi,wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo bèèrè nípasẹ̀ Olúwa,òun ni èmi yóò máa wá kiri:kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwaní ọjọ́ ayé mi gbogbo,kí èmi: kí ó le kíyèsí ẹwà Olúwa,kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹ́ḿpìlì Rẹ.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njúòun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ Rẹ̀;níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ Rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí a ti gbé orí mi sókèga ju ti àwọn ọ̀tá a mi lọ tí ó yí mí ká;èmi yóò rúbọ nínú àgọ́ Rẹ ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tẹ́mi báà ń pè, Áà Olúwa,ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u Rẹ̀”Ojú ù Rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá,
9 Má ṣe fi ojú Rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,má ṣe fi ìbínú ṣá ìránṣẹ́ Rẹ tì;ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,Má ṣe ju mi sílẹ̀, má si ṣe kọ̀ mí,áà Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti bàbá bá kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́júnítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi lọ́wọ́,nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ péèmi yóò rí ìre Olúwaní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn leàní dúró de Olúwa.