1 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2 Nítorí ó yí etí Rẹ̀ padà sí mi,èmi yóò máa, pè é ní wọ̀n ìgbà tí mo wà láàyé.
3 Òkun ikú yí mi ka,ìrora isà òkú wá sórí mi;ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4 Nígbà náà ni mo ké pé orúkọ Olúwa:“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi”
5 Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́ ó sì ní òdodo;Ọlọ́run wa kún fún àánú.
6 Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.
7 Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi Rẹ,nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.
8 Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mikúrò lọ́wọ́ ikú,ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
9 Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwaní ilẹ̀ alààyè.
10 Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé“Èké ni gbogbo ènìyàn”.
12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwanítorí gbogbo rere Rẹ̀ sí mí?
13 Èmi yóò gbé aago ìgbàlà sókèèmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwaní ojú àwọn ènìyàn Rẹ̀.
15 Iyebíye ní ojú Olúwaàti ikú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ̀.
16 Olúwa, ní tòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ ni mo jẹ́;èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ, ọmọ ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ;ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọèmi yóò sì képe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwaní ojú gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwani àárin Rẹ̀, ìwọ Jérúsálẹ́mù.Ẹ yin Olúwa.