Sáàmù 78 BMY

Dídára Ọlọ́run àti Ìfibusú Ísírẹ́lì

1 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;tẹ́tí Rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2 Èmi ó la ẹnu mi ní òweèmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;

3 Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.

4 Àwa kí yóò pa wọ́n mọ́kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,ní fífí ìyìn Olúwa, àti ipa Rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hànfún ìran tí ń bọ̀.

5 Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jákọ́bùo sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì,èyí tí ó páláṣẹ fún àwọn baba ńlá waláti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

6 Nítorí náà àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́nbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí i bítí yóò dìde ti wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn

7 Nígbà náà ni wọn o fi ìgbẹ̀kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́runwọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́runṣùgbọ́n wọn o pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.

8 Wọn ò ní dàbí àwọn baba ńlá wọnìran aláyà líle àti ọlọ́tẹ̀tí ọkàn wọn kò sòòtọ̀ si oloore.

9 Àwọn ọkùnrin Éfúráímù, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun

10 Wọ́n kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin Rẹ̀

11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,àwọn ìyanu tí ó ti fi hàn wọ́n.

12 O ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní agbégbé Síónì

13 O pín òkun níyà, ó sì mú wọn kọjáó mù kí ó nà dúró bá ebè

14 Ní ọ̀ṣán ó fi ìkúùku àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọnàti ní gbogbo òru pẹ̀lú, ìmọ̀lẹ̀ ìná.

15 Ó sán àpáta ní ihàó si fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀bí ẹni pé láti inú ibú wá.

16 O mú ìṣàn omi jáde láti inú àpátaomi sìṣsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò

17 Wọ́n sì tún tẹ̀ṣíwájú láti dẹ́sẹ̀ sí iní ìsọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá ògo ní àgìnjú.

18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wònípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún

19 Wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wí pé“Ọlọ́run ha lè tẹ tábìlì ní aṣálẹ̀?

20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,odò sì ṣàn lọ́pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹó ha le pèṣè ẹran fún àwọn ènìyàn Rẹ̀”

21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù,ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì,

22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́wọn kò sí gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà Rẹ̀

23 Ṣíbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀runó sì sí ilẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;

24 Ó rọ mánà fún àwọn ènìyàn láti jẹ,ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run

25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì;o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó

26 Ó sṣ́ afẹ́fẹ́ ìlà òòrùn láti ọ̀run wáó mú afẹ́fẹ́ gúsù wá nípa agbára Rẹ̀.

27 Ó rọ ọ̀jọ̀ ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyànrìn etí òkun

28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,yíká àgọ́ wọn.

29 Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọnítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọ́n fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,

31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọnó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀.

32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú;nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́

33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asánàti ọdún wọn nínú ìpayà.

34 Nígbà kígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,wọn yóò wá a kirì;wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;wí pé Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn

36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n-ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́nwọ́n fí ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;

37 Ọkàn wọn kò sòtítọ́ si i,wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú Rẹ̀.

38 Ṣíbẹ̀ ó ṣàánú;ó dárí àìṣedédé wọn jìnòun kò sì pa wọn runnígbà kí ì gbà ló ń dá ìbínú Rẹ̀ dúrókò sì rú ìbínú Rẹ̀ sókè

39 Ó ránti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò le padà.

40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ síi ní ihàwọn mú-un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!

41 Síwájú àti síwájú wọn dán Ọlọ́run wò;wọ́n mú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì bínú.

42 Wọ́n kò rántí agbára Rẹ̀:ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,

43 Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ hàn ní Éjíbítì,àti iṣẹ́ àmì Rẹ ni ẹkùn Sáónì

44 Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀;wọn kò le mú láti odò wọn.

45 Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run,àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun.

46 Ó fi ọkà wọn fún láńtataàwọn irè oko wọn fún eṣú

47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ó bá èso sìkàmore wọn jẹ́

48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyínagbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná

49 Ó mú kíkorò ìbínú Rẹ̀ wá sí wọn lára,ìrunú àti ikáánú, àti ìpọ́njú,nípa rírán ańgẹ́lì apanirun sí wọn.

50 Ó pèṣè ipa fún ìbínú Rẹ̀òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikúṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-àrùn

51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin ÉjíbítìOlórí agbára wọn nínú àgọ́ Ámù

52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;ó sọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú ihà.

53 Ó dáàbòbò wọ́n dáadáa, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́nṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

54 Bákan náà ní ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ Rẹòkè tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ tí gbà

55 Ó lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú wọnó sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;ó mú àwọn ẹ̀yà Íṣírẹ́lì jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wòwọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo;wọn kò pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.

57 Gẹ́gẹ́ bí baba wọn, wọn jẹ́ aláìsòdodo gẹ́gẹ́ bi ọrun ẹ̀tàn

58 Wọ́n bí nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;wọn rú owú Rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn

59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,inú bí i gidigidi;ó kọ Ísírẹ́lì pátapáta.

60 Ó kọ àgọ́ Ṣílò sílẹ̀,àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn.

61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

62 Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.

63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

64 A fi àlùfáà wọn fún idà,àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.

65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.

66 Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà;ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé.

67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Jósẹ́fù,kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù;

68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà,òkè Síónì, èyí tí ó fẹ́ràn.

69 Ó kọ́ ibi mímọ́ Rẹ̀, ibí gíga,gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

70 Ó yan Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;

71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntànláti jẹ́ olùṣọ́ Àgùntàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì ogún un Rẹ̀.

72 Dáfídì sì ṣọ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;pẹ̀lú ọwọ́ òye ní ó fi darí wọn.