Sáàmù 62 BMY

Orin Gbígba Ọlọ́run Nìkan Gbọ́

1 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá.

2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;oun ní ààbò mi, a kí yóò sí mi ní pò padà.

3 Ẹ̀yin ó ti máa rọ́lù ènìyàn kan pẹ́ tó?Gbogbo yín ni ó fẹ pa á,bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀ àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

4 Kìkì èró wọn ni láti bì ṣubúkúrò nínú ọlá Rẹ̀;inú wọn dùn sí irọ́.Wọn ń fi ẹnu wọn súre,ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn nínú ọkàn wọn. Sela

5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmí wà, ìwọ Ọlọ́run mi.Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ.

6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;Òun ni ààbò mi, a kí yóò sí mi nípò.

7 Ìgbàlà mi àti ògo mí dúró nínú Ọlọ́run;Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;tú ọkàn Rẹ̀ jáde sí i,nítorí Ọlọ́run ní ààbò wa.

9 Ní tòótọ́, asán ní àwọn ọmọ ènìyàn, èkési ni àwọn olóyè, wọn gòkè nínú ìwọ̀nbákan náà ni wọn fẹ́rẹ̀ jù asán lọlápapọ̀ wọn jẹ èémí.

10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnílára,tàbí gbéraga nínú olè jíjà,nítòótọ́ bí ọrọ̀ Rẹ̀ ń pọ̀ síi,má ṣe gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.

11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mogbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ní agbára

12 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tirẹ ni àánúnitorí ti iwọ san án fun olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ Rẹ̀.