1 Ní Júdà ni a mọ Ọlọ́run;orúkọ Rẹ̀ sì lágbára ní Ísírẹ́lì
2 Àgọ́ Rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù,ibùgbé Rẹ̀ ní Síónì.
3 Níbẹ̀ ní o ṣẹ́ ọfà,asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela
4 Iwọ ni ògo àti ọláJu òkè-ńlá íkogun wọ̀nyìí lọ.
5 Àwọn akíkanjú ọkùnrin A kó àwọn akíkanjú ogun ní ìkógunwọn sún oorun ìgbẹ̀yìn wọn;kò sí ọ̀kan nínú àwọn ajaguntó lè gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfìbú Rẹ, Ọlọ́run Jákọ́bù,àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dúbúlẹ̀ ṣíbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni o yẹ kí a bẹ̀rù.Ta ló lé dúró níwájú Rẹ nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdàjọ́ láti ọ̀run,ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ ẹ́:
9 Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,bá dìde láti ṣe ìdájọ́,láti gba àwọn ẹni ìnílára ilẹ̀ náà. Sela
10 Lóòtọ́, ìbínú Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,ẹni tí ó yọ nínú ìbínú Rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara Rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run Rẹ kí o sì mú-un ṣẹ;kí gbogbo àwọn tí ó yíi kámú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí o tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;àwọn ọba ayé sì n bẹ̀rù Rẹ̀.