1 “Ìba má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”ni kí Ísírẹ́lì kí ó máa wí nísinsìn yìí;
2 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
3 Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láàyènígbà tí ìbínú wọn ru sí wá
4 Nígbà náà ni omiwọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
5 Nígbà náà ni agbéragaomi ìbá borí ọkàn wa.
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́nbí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;okùn já àwa sì yọ.
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,tí ó dá ọ̀run òun ayé.