1 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;Tẹ́tí sí àdúrà mi.
2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,ilé ìsọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ Rẹ títí láékí ń sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá Rẹ.
5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ Rẹ̀.
6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí o gùn,ọdùn Rẹ̀ fún ìrandíran.
7 Kí o máa jọba níwájú Ọlọ́run títí láé;pèsè àánú àti òtítọ́ Rẹ̀ tí yóò máa ṣe ìtọ́ju Rẹ.
8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ títí láékí ń san ẹ̀jẹ́ mí ní ojoojúmọ́.