Sáàmù 55 BMY

Àdúrà Nígbà Tí Ọ̀rẹ́ Bá Dalẹ̀

1 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2 Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo

3 Sí ohùn àwọn ọ̀ta ni,nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí miwọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4 Ọkàn mi wà nínú ìrọra pẹ̀lú;ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5 Ìbẹ̀rù àti ìwàrírí wa sí ara mi;ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7 Èmi ìbá sá lọ jìnnà rérékí ń sì dúró sí ihà;

8 Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,jìnnà kúrò nínú ìjì àti èfúùfù líle.”

9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

10 Ọ̀sán àti oru ní wọ́n fí ń rìn gbogbo odi kiri;àrankàn àti èébú wà láàrin Rẹ̀.

11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárin Rẹ̀;ìdẹ́rùbà àti irọ́ kò kúrò ní ìgboro Rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,èmi yóò fara mọ́ ọn;tí ọ̀ta bá gbé ara Rẹ̀ ga sími,èmi ibá sá pamọ́ fún un.

13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ mi,

14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádún adùn ìdàpọ̀bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwujọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,Kí wọn ó lọ láàyè sí isà òkú,Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.

17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sánèmi sunkún jáde nínú ìpọ́njú,o sì gbọ́ ohùn mi.

18 Ó rà mí padà láìléwukúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19 Ọlọ́run yóò gbọ́ yóò sì pọ́n wọn lójúàní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbà a nì—SelaNítorí tí wọn kò ní àyípadà,tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ Rẹ̀;ó ti bá májẹ̀mú Rẹ̀ jẹ́.

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ̀ kúnná ju òrí àmọ́,ṣùgbọ́n ogun ija wà ni àyà Rẹ̀;ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,ṣùgbọ́n idà fífà yọ ní wọn.

22 Gbé ẹrù Rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwayóò sì mú ọ dúró;òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá miwá sí ihò ìparun;Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tànkì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.