1 Èéṣe tí àwọn orílẹ̀ èdè fi ń dìtẹ̀,àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkísí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọ pọ̀àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀sí Olúwaàti sí Ẹni àmì òróró Rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,”“kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni ó bá wọn wí ní ìbínú Rẹ̀ó sì dẹ́rùba bà wọ́n ní ìrunú Rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipòlórí Síónì, òkè mímọ́ mi.”
7 Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;lónìí, èmi ti di baba Rẹ.
8 Béèrè lọ́wọ́ mi,Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè di ìní Rẹ,òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún Rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọnìwọ yóò sì rún wọn wómú wómú bí ìkòkò amọ̀”.
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n;ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ ṣin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rùẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínúkí ó má ba à payin run ní ọ̀nà yin,nítorí ìbínú Rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi i ṣe ibi ìsádi wọn.