Sáàmù 45 BMY

Orin Ìfẹ́

1 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ reregẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohuntí mo ti ṣe fún ọbaahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

3 Gba idà Rẹ mọ́ ìhà Rẹ, ìwọ alágbára jùlọwọ ara Rẹ̀ ní ògo àti ọla ńlá.

4 Nínú ọlá-ńlá Rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíàlórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣe ohun ẹ̀rù

5 Jẹ́ kí ọfà mímú Rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lujẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀

6 Ìjọba Rẹ Ọlọ́run, yóò pẹ́ títí ayéọ̀pá aládé ni yóò jẹ́ ọ̀pá ìjọba Rẹ

7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburúnígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run Rẹ̀ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀,nípa fífí àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́

8 Gbogbo aṣọ Rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjíá àti alóe àti kaṣíà;láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣeorin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú Rẹ̀ dùn.

9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn aládé wànínú àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúrónínú wúrà ófórì.

10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí Rẹ̀ símigbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ àti ilé baba Rẹ

11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà Rẹ gidigidinítorí òun ni Olúwa Rẹkí ìwọ sì máa tẹríba fún un.

12 Ọmọbìnrin ọba tirẹ̀ yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùnàwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojú rere Rẹ̀.

13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárin ilé Rẹ̀aṣọ ìbalẹ̀ Rẹ̀ a ṣe é lọ́sọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà

14 Nínú aṣọ ìbànújẹ́ iyebíye ni a mú-un wá sí ọ̀dọ̀ ọbaàwọn wúndíá ẹgbẹ́ Rẹ̀ tẹ̀ lé e wọ́n, sí mú-un tọ̀ ọ́ wá

15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùnwọ́n sì wọ ààfin ọba.

16 Ọmọ Rẹ̀ ni yóò gba ipò baba Rẹ̀ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

17 Èmí yóò máa rántí orúkọ Rẹ̀ ní ìran gbogbonígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.