1 Ẹ kíyèsí i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,kí ẹsì fi ìbùkún fún Olúwa.
3 Olúwa tí ó dá ọ̀run Òun ayé,kí ó bùsí i fún ọ láti Síónì wá.