Sáàmù 41 BMY

Ìbùkún Tí Ó Wà Fún Aláàánú

1 Ìbùkùn ni fún ẹni tí ó ń rò ti aláìní: Olúwa yóò gbà á ni ìgbà ìpọ́njú.

2 Olúwa yóò dààbò bòó yóò sí pa ọkàn Rẹ̀ mọ́:yóò bùkún fún-un ni orí ilẹ̀kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá Rẹ̀.

3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn Rẹ̀yóò sì mú-un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn Rẹ̀.

4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mí;wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

5 Àwọn ọ̀ta mi ń sọ́rọ̀ mi nínú arankan, pé“Nígbà wo ni yóò kú ti orúkọ Rẹ̀ yóò sì run?”

6 Nígbà kígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà Rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara Rẹ̀;nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kalẹ̀.

7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;èmi ni wọn ń gbìmọ̀ ibi sí,

8 wọ́n wí pé “Ohun búburú ni ó di mọ́-ọn sinsinàti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,kì yóò dìde mọ́”.

9 Pàápàá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,tí gbé gìgíṣẹ̀ Rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11 Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi,nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

12 Bí ó ṣe tèmi niìwọ dì mí mú nínú ìwà òtítọ́ miìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú Rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lìláé àti láéláé.Àmín àti Àmín.