Sáàmù 118 BMY

Orin Ìṣẹ́gun

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

2 Jẹ́ kí Ísírẹ́lì wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé”.

3 Jẹ́ kí ilé Árónì wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé”.

4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé.”

5 Nínú ìrora mi, mo sunkún sí Olúwa,ó sì dámi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

6 Olúwa, ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.Kí ni ènìyàn lè ṣe si mi?

7 Olúwa n bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ miNítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìfẹ́ mi lórí àwọn ti ó kórìíra mi.

8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwaju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwaju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ aládé lọ.

10 Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yí mi káàkiri,ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò

11 Wọn yí mi ká kiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù

12 Wọn gbá yìnìn yí mí ká bí oyin,ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.

13 Ìwọ tì mi gidigidi kí ń lè subú,ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.

14 Olúwa ni agbára àti orin mi;ó si di ìgbàlà mi.

15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:“ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!

16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbé ga;ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”

17 Èmi kì yóò kú ṣùgbọ́n èmi yóò yè,èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.

18 Olúwa bá mi wí gidigidi,ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òdodo fún mi:èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwaibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.

21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dámi lóhùn;ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22 Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ni ó di pàtàkì òkúta igun ilé;

23 Olúwa ti ṣe èyíó ṣe ìyanu ní ojú wa.

24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú Rẹ̀.

25 Olúwa, gbà wá; Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.

26 Ìbùkún ni fún àwọn tí ó wá ní orúkọ Olúwa.Láti ilé Olúwa wá ní àwa fi ìbùkún fún ọ.

27 Olúwa ni Ọlọ́run,ó ti mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn sí wa lárapẹ̀lú ẹká igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.