1 Láti inú ibú wá níèmi ń képè ọ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,jẹ́ kí etí Rẹ̀ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 Olúwa, ìbáṣe pé kí ìwọ kí o máa ṣàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tà ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdàríjìn wà lọ́dọ̀ Rẹ,kí a lè máa bẹ̀rù Rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,àní ju àwọn ti ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáńdè wà.
8 Òun ó sì dá Ísírẹ́lì ní ìdèkúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ gbogbo.