Sáàmù 86 BMY

Ìpè Fún Ìrànlọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú

1 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dà mí lóhùn,nítorí mo jẹ́ talákà àti aláìní.

2 Dáàbòbò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:ìwọ ní Ọlọ́run mi,gbà ìránṣẹ́ Rẹ làtí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,nítorí èmi ń pe ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ, Olúwa,ní mo gbé ọkan mí sókè sí.

5 Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́,

6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;tẹ́tí sí ẹkún fún àánú.

7 Ní ọjọ́ ipọ́njú mi èmi yóò pe ọ́,nítorí ìwọ yóò dá mí lóhùn.

8 Nínú àwọn òrìṣà kò sì ẹni tí ó dà bí Rẹ, Olúwa:kò sí àwọn iṣẹ́ tí a le fi wé tìrẹ.

9 Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dáyóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, Olúwa;wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀.

10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ní Ọlọ́run.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ;fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ.

12 Èmi o yìn ọ, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkan mi;èmi o fògo fún orúkọ Rẹ títí láé

13 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ̀ si mi;ìwọ ti gba mí kúrò nínú ọ̀gbun ìsà okú.

14 Àwọn onígbéraga ń dojú kọ mí, Ọlọ́run;àti ìjọ̀ àwọn alágbára ń wáọkàn mi kiri,wọn kò sì fi ọ pè.

15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.

16 Yípadà sí mi kí ó sì ṣàánú fún mi;fún àwọn ènìyàn Rẹ ní agbárakí o sì gba ọ̀dọ́mọ̀kunrin ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ là.

17 Fi àmi hàn mí fun rere,kí àwọn tí ó kóriíra mi le rí,ki ojú le tì wọ́n, nítorí iwọni ó ti tù mi nínú.