Sáàmù 91 BMY

Ìdánilójú Ààbò Ọlọ́run

1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ ọ̀gá ògoni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,“Òun ní ààbò àti odi mi,Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

3 Ní tòótọ́ òun yóò gbà mí nínúìdẹkùn àwọn pẹyẹ pẹyẹàti nínú àjàkálẹ̀-àrùn búburú.

4 Òun yóò fi ìyẹ́ Rẹ̀ bò mí,àti ni abẹ́ ìyẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

6 Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn,tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan.

7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ,ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ

8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹàti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò Rẹ,ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ.

10 Búburú kan ki yóò subu lù ọ́Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ.

11 Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹláti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ;

12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ Rẹ̀ gún òkúta.

13 Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀

14 “Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ sì mi,”“èmi yóò gbà ọ́;èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dáa lóhùn;èmi yóò wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ipọ́nju,èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un

16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùnèmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”