Sáàmù 32 BMY

Ayọ̀ Ìdáríjì

1 Ìbùkún ni fún àwọntí a dárí ìrékọjá wọn jìn,tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náàẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ sí i lọ́rùnàti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3 Nígbà tí mo dákẹ́,egungun mi di gbígbó dànùnípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òruọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára;agbára mi gbẹ tángẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn Sela

5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọàti pé èmi kò sì fi àìsòdodo mi pamọ́.Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”ìwọ sì dáríẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí. Sela

6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọní ìgbà tí a le ri ọ;nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela

8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ Rẹ lé ọ̀nà ìwọ yóò rìnèmi yóò máa gbà ọ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

9 Má ṣe dàbí ẹsin tàbí ìbaka,tí kò ní òyeẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,kí wọn má ba à sún mọ́ ọ.

10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣinni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.