Sáàmù 96 BMY

Ìpè Láti Yin Olúwa

1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ Rẹ̀ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3 Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn.

4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ sí;òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìsà lọ

5 Nítorí aṣán ni gbogbo àwọn òrìsà orílẹ̀ èdèṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run

6 Ọlá àti ọlá ńlá wà ni ìwájú Rẹ̀agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ yin ìbátan ènìyànẸ fi agbára àti ògo fún Olúwa

8 Ẹ fi ògo tí o tọ́ sí Olúwa fún un;ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá Rẹ̀

9 Ẹ máa sin Olúwa ninú ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀;ẹ wárìrì níwájú Rẹ̀ gbogbo ayé.

10 Sọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, “Olúwa jọbaa fi ìdí ayé mú lẹ̀, tí kò sì lè yí;ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.”

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì dùnjẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú ohungbogbo tí ń bẹ nínú Rẹ̀.

12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀àti ohun gbogbo ti ń bẹ nínú Rẹ̀:nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀

13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,nítorí ti ó ń bọ́ wá,òun bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayéyóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayéàti ti àwọn ènìyàn ni yóò fí òtítọ́ Rẹ̀ ṣe.