1 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ Rẹ:dá mi láre nípa agbára Rẹ.
2 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3 Àwọn àlejò ń dìde sí mí.Àwọn aláìláàánú ènìyàn ń wá ayé miàwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
4 Kíyèsí i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.
5 Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.
6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọèmi yóò yin orúkọ Rẹ, Olúwa,nítorí tí ó dára.
7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogboojú mi ti wo ìborí lórí ọ̀ta mi.