1 Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde ní Éjíbítì,ilé Jákọ́bù láti inú ènìyàn àjòjì èdè
2 Júdà wà ní ibi mímọ́,Ísírẹ́lì wà ní ìjọba.
3 Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:Jódáni sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí agbo àtiòkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí ìwọ fi wárìrì?Ìwọ Jódánì, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí agbo,àti ẹ̀yin òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;ní iwájú Ọlọ́run Jákọ́bù
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,àti òkúta-ìbọn di orísun omi.