Sáàmù 65 BMY

Ìyìn Yẹ Ọlọ́run

1 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ni Síónì;sì ọ ni a o mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2 Ìwọ tí o ń gbọ́ àdúrà,gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ Rẹ.

3 Ọ̀ràn àìṣedédé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò

4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàntí o mú wa láti máa gbé àgọ́ Rẹ!A tẹ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé Rẹ,ti tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ.

5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohùn ìyanu ti òdodo,Ọlọ́run olùgbàlà wa,ìrètí gbogbo òpin ayéàti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,

6 Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára Rẹtí ó di ara Rẹ̀ ní àmùrè agbára

7 Ẹni tí ó mú ríru omi òkun dákẹ́ríru ariwo omi wọn,àti gìdìgìdì àwọn ènìyàn

8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù agbára Rẹ̀:ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ̀ yọìwọ pé orin ayọ̀ jáde.

9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;ìwọ mú ní ọ̀rọ̀ púpọ̀.Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omiláti pèsè ọkàn fún àwọn ènìyàn,nítorí ibẹ̀ ní ìwọ ti yàn án.

10 Ìwọ fi ìrinmi sí aporo Rẹìwọ tẹ́ ògúlùtù Rẹ;ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ Rẹ rọ̀o sì bùkún ọ̀gbìn Rẹ.

11 Iwọ fi oore Rẹ de ọdún ni adé,ọ̀rá ń kan ni ipa-ọ̀nà Rẹ

12 Pápá-tútù ni ihà ń kán: àwọn òkè kékèké fi ayọ̀ di ara wọn ni àmùrè.

13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà, ni asọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,wọn hó fún ayọ̀, wọn ń kọrin pẹ̀lú.