1 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OlúwaǸjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ Rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìsòótọ́,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìírá àwùjọ àwọn ènìyàn búburúèmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ Rẹ ká Olúwa
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.
8 Áà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé Rẹ ní bi tí ìwọ ń gbé,àní níbi tí àgọ́ ọlá Rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.