1 Èéṣé tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà,ìwọ alágbára ọkùnrin?Oore Ọlọ́run dúró pẹ́ títí
2 Ahọ́n Rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;ó dà bí abẹ mímú,ìwọ ẹni tí ń hùwà ìrẹ́jẹ.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ire lọ,àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,yóò sì dì ọ́ mú,yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó Rẹyóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rùwọn yóò sì rẹ́rìn-ín Rẹ̀, wí pé,
7 Èyi ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára Rẹ̀,bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ Rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀léó sì mu ara Rẹ̀ le nínú ìwà búburú Rẹ̀.
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Ólífìtí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;èmí ní ìrètí nínú orúkọ Rẹ, nítorí orúkọ Rẹ dára.Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.