Sáàmù 74 BMY

Ẹ̀bẹ̀ Fún Ìrànlọ́wọ́ Ní Àkókò Ìdààmú

1 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?Èéṣe tí ìbínú Rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá Rẹ?

2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,ẹ̀yà ilẹ̀ ìní Rẹ, tí ìwọ ti ràpadàÒkè Síónì, níbi tí ìwọ ń gbé.

3 Yí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ padà sí ìparun ayérayé wọn,gbogbo ìparun yìí tí ọ̀ta ti mú wá sí ibi mímọ́.

4 Àwọn ọ̀tá Rẹ ń bú ramú-ramùláàrin ìja ènìyàn Rẹ,wọ́n ń gbé Àṣìá wọn sókè fún àmì;

5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké Rẹ̀ sókèláti gé igi igbó dídí.

6 Ṣùgbọ́n nìsìnsìn yìí iṣẹ́ ọnà fínfínní wọn fi àáké òòlù wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà

7 Wọ́n sun ibi mímọ́ Rẹ̀ lulẹ̀wọ́n ba ibùgbé orúkọ Rẹ̀ jẹ́

8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátapáta!”Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

9 A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;kò sí wòlíì kankanẹnìkan kan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.

10 Àwọn ọ̀ta yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?Àwọn ọ̀ta yóò ha ba orúkọ Rẹ jẹ́ títí láé?

11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ Rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ?Mú-un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ Rẹ kí o sì run wọ́n!

12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára Rẹ;Ìwọ fọ́ orí àwọn abàmì ẹ̀dá nínú omi

14 Ìwọ fọ́ orí Lefiatani túútúú, o sì fi se oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá ti ń gbé inú ìjùTìrẹ ní ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;ìwọ fi ìdí òòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.

15 Iwọ ya orísun omi àti iṣàn omi;Ìwọ mú kí odò tó ń ṣàn gbẹ

16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;ìwọ yà oòrùn àti òsùpá.

17 Ìwọ pààlà etí ayé;Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn Rẹ, Olúwabí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ Rẹ jẹ́.

19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà Rẹ fún ẹranko ìgbẹ́ búburú;Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn Rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.

20 Bojúwo májẹ̀mu Rẹ,nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.

21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjújẹ́ kí àwọn aláìní àti talákà yin orúkọ Rẹ.

22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara Rẹ̀ rò;rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.

23 Má ṣe gbàgbé ohun àwọn ọ̀tá Rẹ,bíbú àwọn ọ̀tá Rẹ, tí ó ń pọ̀ síi nígbà gbogbo.