Sáàmù 21 BMY

Ìdúpẹ́ Fún Ìṣẹ́gun

1 Áà! Olúwa, Ọba yóò yọ̀ nínú agbára Rẹ,àti ní ìgbàlà Rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn Rẹ̀ fún un,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu Rẹ̀. Sela

3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nàìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

4 O ní ọwọ́ Rẹ, ìwọ sì fi fún un,àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

5 Ògo Rẹ̀ pọ̀ nípaṣẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún-un;ìwọ́ sì jẹ́ kí iyì ọlánlá Rẹ̀ wà lára Rẹ.

6 Dájúdájú ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún-un:ìwọ́ sì mú inú Rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u Rẹ̀.

7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;nípaṣẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá ògo tí kì í kùnàkì yóò sípò padà.

8 Ọwọ́ Rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀ta a Rẹ rí;ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò wà àwọn tí o kóríra Rẹ rí.

9 Nígbà tí ìwọ bá yọìwọ yóò mú wọn dàbí ìnà ìléru. Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú Rẹ̀,àti pé iná Rẹ̀ yóò jó wọn run.

10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,àti irú ọmọ wọn kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.

11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọwọ́n sì ń pète ìwà-ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.

12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padànígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ Olúwa, nínú agbára Rẹ;a ó kọrin, a ó yín agbára a Rẹ̀.