Sáàmù 22 BMY

Àdúrà Fún Ìtúsílẹ̀ Ìjìyà Àti Ìkóríra

1 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,àní sí igbe àwọn asọ̀ mi?

2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:àti ní òru èmi kò dákẹ́.

3 Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;ẹni tí ó tẹ ìyìn Ísírẹ́lì dó;

4 Àwọn babańlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un Rẹ;wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójú tì wọ́n.

6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́ kì í sì í ṣe ènìyàn;mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn ẹlẹ́yà àwọ́n ènìyàn

7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí i wọn pé.

8 “Ó gbẹkẹ Rẹ̀ lé Olúwa;jẹ́ kí Olúwa gbà á là.Jẹ́ kí ó gbà a là,nítorí pé ó ni ayọ̀ nínú Rẹ̀.”

9 Ṣíbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;ìwọ ni ó mú mi wà láìléwunígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.

10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wánígbà tí ìyá a mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi

11 Má ṣe jìnnà sími,nítorí pé ìyọnu sún mọ́ tòsíkò sì sí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;àwọn màlúù alágbára Báṣánì rọ̀gbà yí mi ká.

13 wọ́n ya ẹnu wọn, si mi bí i kìn-nìún tí ń dọdẹ kirití ń ké ramúramù.

14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé Rẹ̀.Ọkàn mi sì dàbí i ìda;tí ó yọ́ láàrin inú un mi.

15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mí sì ti lẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16 Àwọn ajá yí mi ká;ọwọ́ àwọn ènìyàn ibi ti ka mi mọ́,Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́ṣẹ̀

17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.

18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọnàní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;Áà Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wa fún àtìlẹ́yìn mi!

20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ kìnnìún;Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ ọ̀ Rẹ láàrin arákùnrin àti arábìnrin mi;nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.

23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹyìn-ín!Gbogbo ẹ̀yin ìran Jákọ́bù, ẹ fi ògo fún-un!ẹ dìde fún-un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú ọmọ Ísírẹ́lì!

24 Nítorí pé òun kò ṣááta, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíraìpọ́njú àwọn tí a ni lára;kò sì fi ojú Rẹ̀ pamọ́ fún miṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹsẹ̀ ìyìn mi nínú àwùjọ ńlá yóò ti wá;ẹ̀jẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù Rẹ̀

26 talákà yóò jẹ yóò sì yó;àwọn tí n wá Olúwa yóò yinjẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ̀ wà láàyè títí ayárayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántíwọn yóò sì yípadà sí Olúwa,àti gbogbo ìdílé orílẹ̀ èdèni wọn yóò jọ́sìn níwájú Rẹ̀,

28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀ èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àṣè, wọn yóò sì sìn;gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájúu Rẹ̀àti ẹni ti kò le pa ọkàn ara Rẹ̀ mọ́ ni ààyè.

30 Irú ọmọ Rẹ̀ yóò sìn-in;a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ nípa Olúwa,

31 Wọn yóò polongo òdodo Rẹ̀sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,wí pé òun ni ó ṣe èyí.