Sáàmù 48 BMY

Ògo Àti Agbára Síónì

1 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí o sì yẹ láti máa yìnní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ Rẹ̀

2 Ó dára nínú ipò ìtẹ́ Rẹ̀ayọ̀ gbogbo ayéòkè Síónì, ní ìhà àríwání ìlú ọba ńlá.

3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin Rẹ̀;ó fi ara Rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ

5 Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́na yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ

6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí

7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Táṣíṣìwọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà oorùn.

8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,Ní ìnú Olúwa àwọn ọmọ ogunNí ìlú Ọlọ́run waỌlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela

9 Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́runàwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ

10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ Ọlọ́runìyìn Rẹ̀ dé òpin ayéọwọ́ ọ̀tún Rẹ kún fún òdodo

11 Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùnnítorí ìdájọ́ Rẹ̀.

12 Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀,ka ilé ìsọ́ Rẹ̀

13 Kíyèsí odi Rẹ̀kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayéÒun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.