Sáàmù 7 BMY

Ẹ̀bẹ̀ Fún Ìrànlọ́wọ́ Ní Àárin Ọ̀ta

1 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú Rẹ;gba mí là kí o sì tú mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,

2 kí wọn ó má bá à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìúnwọn a ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gba mí.

3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyítí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi

4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mití mo ja ọ̀ta mí lólè láìnídìí:

5 Nígbà náà jẹ́ kí ọ̀ta mi le mi kí wọn sì mú mi;jẹ́ kí òun kí ó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela

6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú Rẹ;dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀ta mi.Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.

7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yí ká.Jọba lórí wọn láti òkè wá;

8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.

9 Ọlọ́run Olódodo,Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburútí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

10 Aṣà mi ní Ọlọ́run tí ó gajù,ẹni tí ń dáàbò bo àwọn ẹni gíga nípa ti èmi.

11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ tòótọ́,Ọlọ́run tí ń sọ ìrúnú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.

12 Bí kò bá yípadà,òun yóò pọ́n idà Rẹ̀ múó ti fa ọrun Rẹ̀ le náó ti múra Rẹ̀ sílẹ̀

13 Ó ti pèṣè ohun ìjà ikú sílẹ̀;ó ti pèṣè ọfà iná sílẹ̀.

14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,tí ó sì lóyùn wàhálà ó bí èké jáde.

15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jádejìn sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.

16 Wàhálà tí ó fà padà sórí Rẹ̀;Ìwà ipá Rẹ̀ padà sórí ara Rẹ̀.

17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo Rẹ̀Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa tí ó ga jùlọ.