Sáàmù 49 BMY

Òmùgọ̀ Tí Ó Wà Nínú Ìgbẹ́kẹ̀lé Ọrọ̀

1 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé

2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kérétalákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!

3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́nìsọ láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4 Èmi yóò yí etí mi sí òweolókùn ni èmi yóò ṣi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mí sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

5 Èéṣé ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi déNígbà tí àwọn ènìyàn búburú àti ayan nijẹ yí mi ká,

6 Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọntí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn

7 Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì Rẹ̀padà tàbí san owó ìràpadà fúnỌlọ́run.

8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ iyebíyekò sì sí iye owó tó tó fún sísan Rẹ̀

9 Níti ki ó máa wà títí ayéláì rí ìsà òkú.

10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kúbẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú sègbéwọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn

11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláéibùgbé wọn láti ìrandé ìranwọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́o sì dàbí ẹranko tí o sègbé

13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ogbàgbọ́ nínú ara wọn,àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,tí o gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela

14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkúikú yóò jẹun lórí wọn;ẹni tí ó dúró ṣinṣin ní yóòjọba lórí wọn ní òwúrọ̀;Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padàkúrò nínú isà òkúyóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara Rẹ̀.

16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi

17 nítorí kì yóò mú òun kan dání nígbà tí ó bá kú,ògo Rẹ̀ kòní báa sọ̀kálẹ̀ sí ipò òkú

18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara Rẹ̀.Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere

19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba Rẹàwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.