1 Èmi o yìn ọ, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;Èmi o sọ ti ìyanu Rẹ gbogbo.
2 Inú mi yóò dùn èmi yóò sì yọ̀ nínú Rẹ;Èmi o kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3 Àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà;Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú Rẹ.
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀ èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀ta,Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;Àní ìrántí wọn sì ti sègbé.
7 Olúwa jọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́,èmi tàbí ìwọ, Olúwa, kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ti o ń jọba ní Síónì;kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀ta ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí o lè sọ ti ìyìn Rẹni ẹnu ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Síónìàti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ.
15 Àwọn orílẹ̀ èdè ti jìn sí kòtò ti wọn ti gbẹ́;ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo Rẹ̀;àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a ò ní gbàgbé láéláé,ìrètí àwọn ti ó talakà lójú kí yóò ṣègbé láéláé.
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀ èdè ni iwájú Rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela